Yíy Ìdènà, íègbéga Ìe

Papa Omotayo

October 28, 2022

Lagos, Interdependence

The doorway to CCA, Lagos. Image by author.
The doorway to CCA, Lagos. Image by author.

Mò ń gbìyànjú láti tọ ipasẹ̀, ìrántí ìrírí ìgbà tó dùbúlẹ̀ síbìkan láàárín àwámárìídìí àti ìgbé-ayé ẹlòmìíràn. Wákàtí ti kọjá lọ, ìrìn, ní àwò díẹ̀, ṣíṣèdákọjá Muritala Muhammed Way àti àwọn ọ̀na kọ̀ọ̀rọ̀ ti agbègbe gúúsù ní Yaba tí o di ibùdó onítàn Ebutte Metta, ibùdó àwọn eèyan Yorùbá tíí ṣe ẹ̀ya Ẹ̀gbá láti Abẹ́òkúta. Wọ́n bí mi sí Àdúgbò Borno.

Mo ti wá láti ilé mi, ní Gbagada. Tí o bá gbìyànjú láti tọ ipasẹ̀ mi o ó lọ lọ́nà àríwá ní Ọ̀na Ìkòròdú, tó jìn ju Jíbówú lọ, Palm Groove, Ṣómólú àti Ọbaníkòró, tó jìn ju ìrúró Shepherdhill Baptist Church.

Ní ìsáré mi, láàárọ̀ yìí, ọwọ́ ní orúnkún mi, mímú èémí mi, ṣíṣẹ̀yì kọ́dọ́rọ́, léyìí tí mo ti sọ ìṣíṣẹ-n-tẹ̀lé ìdún mi nù, mo dúró ní ilé ìjọsìn náà lójijì. Ojú àti orí ì mí wòye, bíi pé ó ń ṣẹ̀da átífáàtì. Mo nímọ̀sílára ṣíṣí àti ìṣàn, léyìí tí a ń pẹ̀ jáde. Ọ̀rọ̀ náà “Shepard Hill” jẹ́ èyí tí a kọ jáde gbàgàdà pẹ̀lú ọ̀dà funfun sórí UFO aláwọ̀-ilẹ̀, irin, tẹ́ẹ̀ǹì-ajọ àjà, léyìí tó jọ èyí tó wà lágbedeméjì, ló létéńté sílẹ̀, tó ṣetán láti lọ sí ọ̀run nígbàkúùgbà.

Yóò ti dára kí n pe ọmọ̀yákùnrin mi láti bèrè orúkọ àdúgbò náà. Ṣùgbọ́n ohun tó níṣe pẹ̀lú àìrántí àdìrẹ́ẹ̀sì ní pàtó nía ibi tí mo gbé di ọmọ ọdún mẹ́fà, àti ibi tí bàbá mi gbé di ọjọ́ ikú rẹ̀, kódà lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún, tinu lójú púpọ̀.

Rárá, èyí kìí ṣe Simpson. Rárá, kìí ṣe Adékúnlé. Kìí ṣe Carter. Rárá, kìí ṣe McCullum bákan náà. Gbogbo orúkọ wọ̀nyí—Carter, Simpson—dún bíi àjèjì, àwọn “ìyókù” Kìí ṣe orúkọ ibi tí bàbá mi yóò yàn láti gbé. Ṣùgbọ́n Alágoméjì ni. Ibùsọ̀ náà nìyí. Mo dúró ni Àdúgbò Borno. Ṣé ibí ni? Mo ò mọ̀ dájú. Ilé tí mò ń wá wà níbi tí mo ti rí àdúgbò náà pọ̀ ní ayẹyẹ eégún, amúlùúdùn, ati òde àdúgbò; pẹ̀lú ìmìtìtì àti ìdùnú ìṣe àwọn àdúgbò náà. Ibẹ̀ ni mo ti kọ́kọ́ gba atẹ́gùn tútù ayé nígbà tí oòrún lọlẹ̀, yíyọ́ lọ sísàlẹ̀ láti sá pamọ́ sábẹ́ ìgùnsókè ilé lẹ́gbẹ́ẹ igunlé àti láti gbọ́ bí àwọn àgbá ṣe ń sọ ìtàn.

Ó ti rẹ̀ mí.

Mo pe ọ̀rẹ́ mi mìíràn lórí ìbánisọ̀rọ̀, Fọlárìn, mo sì bèrè bó bá mọ ibi tó súnmó láti lọ ẹ̀rọ alátagbà, ṣùgbọ́n tí yóò dákẹ́ jẹ́ láti lè kàwé àti láti ṣiṣẹ́ díẹ̀. Èní kìí ṣe ọjọ́ tí mo fẹ́ láti wà nínú ọ́fíìsì. Lóríi Google Map báyìí, ó sọ pé ibùdó náà wà ní òkèrè tó lè gbà tó ìṣẹ́jú ìwákọ márùn-ún.

Fọ́lárìn fún mi ní ìpèjúwe ọ̀nà: “Lọ sí Old Yaba Road, láti ibi tí o wà. Yóò tọ́ ẹ lọ sọ́nà ìbẹ̀rẹ Herbert Macauly (léyìí tó papọ̀ mọ́ àwọn tíí lọ tíí bọ̀ láti Island). Yà sí apá ọ̀tún sí Àdúgbò Hughes, òsì sí Àdúgbò Queens, o ó sì rí ní ìgbẹ̀yìn, ní iwájú rẹ. Ní Àdúgbò McEwen! Ó ní ìlà ńlá méjì wọ̀nyí tí ó gbé ilé òkè dúró.” Ó fẹ́ pa ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà ṣùgbọ́n ó ṣe àfikún pé, “wàyí o, ìsọ tí wọ́n ti ń ṣẹ̀då̀ ìwé wà sí ìsàlẹ̀ ilé náà. Ǹjẹ́ o lè bá mi wò bí ìtẹ̀jáde mí ti wà ní ṣíṣetán? Wọ́n sọ pé ó ti ṣetán, àmọ́ ah, ẹ̀bẹ̀, kàn wò wọ́n fún mi. O ṣé ọ̀rẹ́. Jẹ́ kí mo mọ ohun tí o rò nípa CCA.” Ó si pa ẹ̀rọ náà.

Kàyéfì àkọ́kọ́ ní ilé ayé máa ń wà, léyìn náà àlàyé nípa rẹ̀.

Fọlárìn Shasanya, olùyàwòrán, ṣe sọ lẹ́tà mẹ́ta, “CCA,” kò si ṣàlàý rẹ̀. Mo lọ láìròtẹ́lẹ̀. Nígbà tí mo sì dé, lẹ́ẹ̀kejì lọ́jọ́ náà, àlejò kán kojú mi ní ilé kan. Yaba, ibi tí kò lérò púpọ̀ tó yí mọ́ àwọn ilé ìgbé ajẹmọ́ ìtàn àwọn amúnisìn àti léyìn-1950, àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ilé náà ti di pípàrọ̀ tàbí wíwó fún ìkọ́ àwọn ilé ajẹmájé.

The CCA, Lagos. Image by author.
The CCA, Lagos. Image by author.

Ilé tí mo dé sí kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣérí, alwọn ilé akọ́ pẹ̀lú àra-1960s wà légbẹ̀ẹ́ méjéẹ̀jì. Ilé náà jókòó láàárín ìlà ilé tó wà ní ìràn-ẹsẹ̀ ilé Lagos: 18.3 mítà ní gígùn àti 36.6 mítà ní jíjìn.

Ilé náà jẹ́ èyí tí a kùn ní ọ̀da kíríìmù hue láàárín ọ̀pọ èyí tí a kùn, ògiri tí a rẹ́ pẹ̀lú sìmẹ́ǹtì ní Lagos. Ó jọ bíi pé a ti húnpọ̀ béè látilẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi oníṣe, ogiri gbọọrọ láti lẹ̀ jẹ́ kí ìlo rẹ̀ peléke. Ó gan ní alájà mẹ́rin, pẹ̀lú àjà kọ̀ọ̀kan tó ní ní pánẹ́ẹ̀lì ńlá tí a gé látara ọwọ́ iwájú rẹ̀. Nítorí Lagos ni èyí, ìkọ́ ọ “ghen gehn” rẹ̀ wá látara àja kẹta, léyìí tí òpó mẹ́rin gbámú; ìjísọ sí ìṣe àwọn ará Rome àti Greek, léyìí tí ó ṣe àwọn ìkọ́ ìwúrí tó jọra tó bẹ̀rẹ̀ sí wà káàkiri ilétéńté ojú ọ̀run Lagos láti 1990s.

Àjà kẹrin tún jẹ́ èyí tí a fà sẹ́yìn látara ògiri náà, ìyàwòrán àpẹẹrẹ tó ṣẹ̀dá ìkọjúsíra ìdì ìlà gbọọrọ méjì tó lọ láti fífẹ̀ iwájú ìta náà. Ìdì àkọ́kọ́ náà lọ jáde láti ìjìnlẹ̀ igun kan, nígbà tí èkejì láti òtéńté ilé tí ó sì pèse ojúnà ìgbáfẹ́, ọ̀kan lára àwọn ibi tí mo fẹ́ràn fún àwọn ènìyàn láti wo ìlú náà.

View from the CCA, Lagos. Image by author.
View from the CCA, Lagos. Image by author.

Ó jẹ́ ilé tí ó ṣòro láti ṣìnà. Òótọ́ ni Fọlárìn sọ. Èyí jẹ́ ọ̀rọ̀ ọmọlúàbí láti lè ṣèto ibi àti ìlànà àti le tètè ráńtí.

Ó ti kọjá 11am. Mo ní ìmọ̀sílára ìdìde àti ìrìnká àwọn ènìyànn àti ohùn wọn bí mo ṣe ń rìn lábẹ́ igun àti àwọn ilẹ̀kùn onígíláàsì tí a fi alumínúọ́ọ̀mù ṣe. Mo kí olùṣọ́lé tó jókòó sábẹ́ ìtẹ̀gùn -ilé náà. Ẹyinjú rẹ̀ dàbí èyí tí kò tíì rí orun, àmọ́ ó gbìyànjuh láti dáhùn dáadáa “Ẹ Káàárọ̀ Sà!” padà.

Mo rìn kọjá ibìkan ṣoṣo tó ṣí sílẹ̀ tíí ṣe ilẹ̀kùn sí apá òsì, tó kọjú sí ibi àtẹ̀gùnilọsókẹ̀ ilé náà. Kò sí ẹyà ara mi tó wà ní ìgbaradì fún ìpòpọ̀ atẹ́gùn wọ́ọ́rọ́ àti ìtẹ̀jáde ìhó íǹkì tí ó dà bíi pé ó wọnú ọpọlọ mi lọ.

Mo bọ́ta padà mo sì bi olùṣọ́lé náà, “CCA náà?” Ó dáhùn, “Ìyẹn ni àjà tí ó tẹ̀lé ìyẹn.”

Mo rìn lọ sókè mo sì ríi. Yàrá tí ó kún fún ìwé nípa iṣẹ́ ọlnà, ìhunpọ̀, ìyàwòrán, ìyalé, àti ìṣe.

Periodicals at the CCA, Lagos. Image by author.
Periodicals at the CCA, Lagos. Image by author.

Kàyéfì àkọ́kọ́ ní ilé ayé máa ń wà, léyìn náà àlàyé nípa rẹ̀.

Mo nímọ̀sílára bíi pé àsìkò pípẹ́ ti ré kọjá kí mo tó gbé báàgì mi sílẹ̀. Lọ́kọ́ọ̀kan, ẹsẹ̀ mi ń wọ́lẹ̀ ojú mi sì ń yàwòrán, nísìnyí ní ṣẹ́líìfù àti ríìmù ìyídò. Monogíráàfù, Bayógíráhíìsì, ìtòjọ ẹsibíṣọ́ọnù, àròkọ, tíọ́rì pàtàkì, jọ́nà, àti magasíìnì láti gbogbo ibi káàkiri àgbáyé. Ìwé ọ̀rọ̀bọ̀, lẹ̀pa, arúgbọ́, tuntun. Pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Áfíríkà èyí… Áfíríkà ìyẹn!

Tí i bá kọ́ ọ, wọ́n ma wá. Ṣùgbọ́n màá dé ibẹ̀ tó bá yá.

Center for Contemporary Art, Lagos (CCA) jẹ́ èyí tí a ṣẹ̀dá bíi àyè aláì-mẹ́rè-wá, gálárì, yàrah ìkàwé àti gbọ̀gan ìkẹ́kọ̀ọ́ ní 2007, ọdún kan ṣáájú kí mo tó lọ síbẹ̀. Ẹ̀róńgbà rẹ ni láti jẹ́ kí àwọn o0hùn tuntún dìde pẹ̀lú àwọn ọ̀ye ayàwòrán ọ̀tun àti ìgbékalẹ̀. Àyè fún àwọn olùgbé Èkó láti wá, ṣàpérò, kọ́, àti pín látara ìmọ àtinúdah tí wọ́n ní àti ìmọ̀ọ́ṣe tó ti wà ní ìlú náà àti àwọn ibòmìíràn jínjìn réré.

Mo mọ CCA ní òpin 2018 nígbhà tí mò ń ṣiṣẹ́ lórí àkànṣe iṣẹ́ ìyàwòrán-ilé mi àkọ́kọ́ ní Abẹ́òkúta. Nígbà náà ẹ̀mi ni olórí ẹ̀ka Lagos fún bukka, ẹgbẹ́ ìwádìí ìyàwòrán-ilé àti ẹ̀kọ́ t́ mo dá sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ mi ní London láti ṣèwádìí lórí àwọn ìlú tí wọ́n ṣẹ̀ ń gbèrú nínú àwọn ohun amáyédẹrùn. Àmọ́ ní ojú ayé, mò ń lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò mi láti ṣèdá àwọn ohun àtinúdá láti lè jẹ́ kí wọ́n di ohun tó ṣeé rí lọ́jú ayé tó rọ̀mọ́ àwọn ohun bíi iṣẹ́ ọnà, ìṣe, àti oríṣiríṣi àkọsílẹ̀ ìtẹ̀jáde, tó wáyé láàárín àwọn ọ̀rẹ́ mi, Fọlárìn àri Simi (àwọn méjéjìí ń ṣiṣẹ́ ní Kachifo Publishing) Bobs (ọmọ̀yákùnrin mi), TC, Tóbi, àti Gbénga, àti àwọn mìíràn. Àtẹ̀jíṣẹ́ máa ń wọlé sórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, íńbọ́ọ̀sì, àti gchat.

Ǹjẹ́ o lẹ̀ bá wa ṣe Lagos Ragatta? Àjọ̀dún Balck Heritage Festival ńkọ́? Ṣé o ti gbọ́ nípa Legacy? Ǹjẹ́ ò ń bọ̀ ní ìṣí Jaekel House? Jẹ́ ká ṣe ìhúnpọ̀ iwájú ìwé fún ìwé Chimanda tuntun fún Kachifo? Jẹ́ ká ṣe álíbọ́ọ̀mù? Ṣé ká ṣe àjọ̀dún iṣẹ́ ọnà ní àdúgbò? Bí a bá gba èèyàn láti wá láti ṣẹ̀dá nǹkan kó sì pín-in… lójojúmọ́ di ìgbàkúgbà!

Gbógbo nǹkán rí bíi pé ó ṣẹlẹ̀ ní ojú ẹsẹ̀. CCA náà farabalè ó sì wà ní ṣíṣe-n-tẹ̀lé.

CCA náà jẹ́ ẹgbẹ́ tí ó wà nítorí ẹni tó ní ojú inú, olóògbé aṣàkójọpọ̀ Bisi Silva, ẹni tó dolóògbé ní ọjọ́ 12 Èrèlé, 2019 ní Lagos. Ó jẹ́ ọmọ ọdún 56. Ó ṣòro láti sọ̀rọ̀ nípa CCA, àti àwọn ìpẹ̀ka iṣẹ́ onà ìyàwòrán ní Lagos, kí a bá dúró sí abẹ́ ìyé apá òjìjí Bisi Silva. Ìyé yìí nà káàkiri tí kọ fi mọ ní àwọn àye iṣẹ́ ọnà ìyàwòrán nìkan jákèjádò ìlú náà: wọ́n tún pẹ̀ka dé àwọn agbègbè ajẹmọ́tàn ètò ẹ̀kọ́ àti Yaba School of Technology àti University of Lagos, lẹ́yìí tọ́ ní ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ ọnà àti ọgbọ́n àtinúdá.

Bisi Silva mẹ́nu bàá lọ́pọ̀ ìgbà ìdí ti ọwọ́ pọ́kú àti ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí ṣe jẹ́ ara ìdí láti yan Yaba gẹ́gẹ́ bí ibùdó CCA, tí kìín fi ń ṣe àwọn ibùdó tí àwọn ẹni ara iṣẹ́ ọnà máa ń wà bíi Lagos Island. Èyí jẹ́ ìgbà tí Yaba kò tíì di gbòògbun iṣẹ́ ẹ̀rọ ayélujára aládàáni ní agbègbè náà. Àwọn àyípadà ní àwọn ilẹ̀ ìlú yìí jẹ́ lára èsi àwọn ilẹ́ iṣẹ́ bíi CCA àti CC Hub (ọ̀kan lára àwọn ilé iṣẹ́ akọ́nilẹ́rọ) tí wọ́n ń pèsè agbègbè fún ọgbọ́n àtinúdá, ìkẹ́kọ̀ọ́, àti ìdókòwò nínú iṣẹ́ ìmẹ̀rọ àti àtinúdá. Ó tún níṣe pẹ̀lú pé, nígbà ta wà pẹ̀lú CCA, Ngozi Odita pèse Lagos gẹ́gẹ́ bíi ibùdó fún ayẹyẹ “Social Media Week” lágbàáyé ní ọdún 2012, ó sì tèsíwájú láti dá ẹgbẹ́ ọlọ́dọọdún nípa àpejọpọ̀ onímọ̀ nípa ìmẹ̀rọ àti ìkànni ayélujára, ìpolówó, àti ìmọọra Africa NXT. Ìtàkurọ̀sọ lórí ìwé orí ẹ̀rọ ti Obidike Okafor ní 2009 kọ ọ̀rọ̀ tí Silva sọ pé A j́ ibùdó ìḱniním̀ a kìí e ti ìpawó.1Obidike Okafor, “Bisi Silva’s Art Place,” On Arts & Visual Cultures in (Northern) Nigeria (blog), 26 June, 2009,.

The library at the CCA, Lagos. Image by author.
The library at the CCA, Lagos. Image by author.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ibùdó gígùn CCA, tó tẹ́ẹ́rẹ́ ti wà ní dídè pẹ̀lú àwọn ìjókòó oníke tí ó sì ní àwọn ọrùn bíi ti adìyẹ tí ó kọjú sí amohùnmáwòrán tàbí àwọn àlejò tí yóò báwa sọ̀rọ̀. Ìtàkurọ̀sọ kún gbogbo inú yàrá ìṣayẹyẹ àwòrán náà, ìgùnsókè arailé, yàrá ìkàwé, bí Àríwá àti Gúúsù ayé ṣe ń pàrọ̀ èrò, àmọ́ ní àye “wa” àti àlayé “wa”. CCA náà bi àwa ayàwòrán, onírònú, aṣàkójọ, òǹkọ̀wé, akọ́mọlẹ́kọ̀ọ́, àti àwọn àlejò láti sọ ìtan tiwa nípa ìbéèrè tó rọ̀ yìí: kí i iṣẹ́ ọnà lè sọ tó sì lè yí padà, níbí?

Láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, CCA ti ní òye ìdí tí ó fi nílò láti ṣẹ̀dá àwòṣe ẹka ètò-ẹ̀kọ́ tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, tí ó mú ìlànà ètò-ẹ̀kọ́, ì̀kànsáwùjọ, àti ìhìnrere wọnú ara wọn. Ó ṣègbédìde àwọn ètò, àwọn ìṣàfihàn, ó sì ń mú ìlọsíwájú bá àwọn ìṣe tí ó tayọ ẹnu odi yàrá-ìyáwèé-kàwé ti ìbílẹ̀ àti ààyè ìṣàfihàn iṣẹ́ ọnà. Gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀ka ètò-ẹ̀kọ́, CCA fẹ́ yọ àwọn ìdíwọ́ ìwọṣẹ́ iṣẹ́-ọnà ṣíṣe, wọ́n sì ń ríi dájú pé iṣẹ́-ọnà ṣíṣe ń ní ìgbéga àti iyì, ní ti àròjinlẹ̀ àti ọgbọ́n síbẹ̀. Ìráyèsí láìsí ìdíwọ́ jẹ́ gbogbogbò, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ òun ni ìpèsè ààyè tó ń kọ́ni nípa àwọn òpó ètò-ẹ̀kọ́ tí ó wà nídìí iṣẹ́ ọnà ṣíṣe, bíi: Bí a ṣe le kọ̀wébèèrè fún ìgbọ̀wọ́? Bí a ṣe le kọ̀wébèèrè fún ìwé-ìgbélùú? Bí a ṣe lè ṣe iṣẹ́ ìwádìí? Bí a ṣe lè ṣàfihàn ètò? Bí a ṣe lè kọ nípa iṣẹ́-ọnà? Bí o ṣe lè sọ nípa iṣẹ́ rẹ? Bí a ṣe le pawọ́pọ̀ ṣe nǹkan? Ohun tí o le ṣe pẹ̀lú àwọn èròjà? Ààtò iye àwọn ètò tó kù póríṣiríṣi síbẹ̀ ó ṣe déédé, pẹ̀lú àwọn tuntun tí a gbémì pẹ̀lú ìlókun nínú àti ìtànmọ́lẹ̀ sí bí ojú-ọjọ́ wa ṣe lè rí.

Láìpẹ́ yìí, nínú oṣù Èbìbí, ọdún 2022 ní ibi ìṣàfihàn Wolfgang Tillmans ní CCA, Mo sún ṣẹ́yìn láti wo ìrọ̀rùn pẹ̀lú ààyè tí a kó tọkàntara àwọn ọ̀dọ́-langba sí, bí kò ṣe ṣe déédé, àti nínú àríwísí àrà, àwọn ọ̀nà àti àwọn ìgbésẹ̀ ayàwòrán. Èyí jẹ́ iṣé tí ó jọ èyí tí a ti rí rí, kódà pẹ̀lú àwọn ìyàtọ̀ nínú sàkáání àti àkókò. Púpọ̀ nínú àwọn àrà àti èdè Tillmans ni wọ́n ṣàfihàn nínú àfihàn náà tí ó ti wà lórí pẹpẹ CCA ní ó lé ní ọdún mẹ́wàá báyìí. ̣

Ọ̀wọ́ náà ṣe àfihàn, “Identity: Imagined States” nínú oṣù Ọ̀wàrà ní ọdún 2009, ó jẹ́ àfihàn iṣẹ́-ọnà onífídíò àkọ́kọ́ tí Mo rí ní ìpínlẹ̀ Lagos. Ní àfikùn sí àwọn àyẹwó náà, ìṣàfihàn iṣẹ́-ọnà náà ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àkọsílẹ̀, ìjíròrò àwọn olùbéèrè, àti àwọn ìtàkùrọ̀sọ. Lagos Photo, tí African Artists Foundation (AAF) fi lọ́lẹ̀ ní ọdún 2010, ni mo lérò pé ó gbọdọ̀ jẹ́ ìtẹ̀síwájú èyì, tí o ń gbé ọ̀pá ìdárí yìí tí ó sì ń ṣàfihàn ìwọ̀n àwòrá àti fíìmù tirẹ̀ tó tayọ.

Kò ṣeéṣe láti ronú ohun tí ò bá jẹ́ àwòkọ́ṣe ti J. D. ‘Okhai Ojeikere láiṣe àtẹ̀jáde ìwé OJEIKERE (2014), àkọsílẹ̀ oníkókó kan náà nínú èyí tí Bisi Silver àti CCA fi ìdí ìṣe rẹ̀ múlẹ̀ labẹ́ ìtàn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìpolongo ìbẹ̀rẹ̀ tí a lò fún àwọn ìkówójọ fún àtẹ̀jáde náà jẹ́ àkọ́kọ́ mìíràn nínú ìṣàfihàn bí àwọn ẹka-ẹ̀kọ́ àṣà ní orílẹ̀-èdè Nigeria àti apá ilẹ̀ tí ó wà ṣe lè sún súrò ní àwọn àwòṣe ìkówójọ ti ayé ìbílẹ̀.

“On Independence and the Ambivalence of Promise” jẹ́ àfihàn tí a ṣe ní CCA ní ọdún 2010 láti fi ṣààmì ayẹyẹ àádọ́ta ọdún òmìnira orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìlànà àti ìṣèṣètò ìsàfihàn ọlọ́dún-gígùn yìí jẹ́ àmì ìfàwòránhàn gidi ní ojú-ọjọ́ iṣẹ́-ọnà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ó sì mú oríṣìíríṣìí ọ̀wọ́ àwọn ohùn àti àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wọlé fún CCA káàriri orílẹ̀-èdè, apá ilẹ̀ tí ó wà àti ìhà Àríwá Àgbáyé.

Ní dún 2012 Wura-Natasha Ogunji wá sí CCA nípa ̀ḱ-̀f́ Guggenheim ó sì e ìdásíl̀ àwn ètò àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́, bí i Lagos: Actions and Archives p̀lú Ọ̀mọ̀wé Peju Olayiwola, láti mú àwọn akópa wọlé sí ìṣe àti oríṣìí eré-ṣíṣe.2These were done on behalf of the CCA at the Visual Arts Gallery, Department of Creative Arts (by the Botanical Gardens), University of Lagos. Ogunji tẹ̀síwájú láti jẹ́ pàtàkì sí eré-ṣíṣe ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nípasẹ̀ àjọ rẹ tuntuṇ Treehouse, ó sì ti ṣe ìtọ́sọ́nà àti àmójútó àwọn ọ̀dọ́-langba oníṣẹ́ ọnà ní àwọn ètò bíi ARTX Prize àti ètò eré-ṣíṣe fún ti abala 2019. Ó tẹ̀síwájú láti pèsè ààyè fún ìfàgùn àwọn ìtàkurọ̀sọ àti àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ láàrin ìṣọwọ́-ṣiṣẹ́ àti iṣẹ́-ọnà olórísiríṣi-ẹ̀ka.

Àjọ CCA ti ṣẹ̀dá ààyè sílẹ̀ fún ìjíròrò àgbájọ àti alábalasábala láti ara ìfẹ̀họ̀núhàn owó ìrànwọ́ orí epo Ẹ Yabo Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti oṣù kíní ọdún 2012 èyí tí ó dá orílẹ̀-èdè náà gúnlẹ̀. Ètò ọjọ́ kan tó ní ìṣàfihàn àwòrán nínú láti ọwọ́ àwọn oníṣẹ́-ọnà bí i Uche James Iroha, Andrew Esiebo, àti Victor Ehikhamenor. Nígbà tí a sì wo ìwọ́de #EndSARS ọdún 2020, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ni wọ́n lo iṣẹ́-ọnà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìgbéròjáde tààrà. Àwo-ojú LED ńlá jẹ́ gbígbékalẹ̀ sí ibùdó Lekki toll gate láti ṣàfihàn iṣẹ́-ọnà, àwòrán, àti àwọn fíìmù tí wọ́n ń dáhùn sí ìfẹ̀hònúhàn ní àsìkò tó yẹ.

Láàrin àsìkò ọdún márùn-ún láti ọdún 2009 àti 2014, Mo ní àǹfààní látí rí àwọn iṣẹ́ CCA ti Anatsui (“Playing with Chance,” 2014), Kelani Abass (“Àsìkò: Evoking Personal Narratives àti Collective History,” 2013), àti àwọn ayàwòrán bíi Uche Iroha, Adolphus Opara, àti George Oshodi. “The Progress of Love” (2013) jẹ́ àwọn ìfihàn tó ṣàfihàn àwọn oníṣẹ́-ọnà obìnrin bíi Valarie Oka, Wura-Natasha Ogunji, Temitayo Ogunbiyi, Zanele Muholi, àti Adaora Nwandu, tí ó fi mọ́ Jelili Atiku pẹ̀lú Andrew Esiebo. Mo rántí àwọn ìtàkurọ̀sọ pẹ̀lú Ruby Onyinyechi Amanze dáadáa, àti àwọn òǹkọ̀wé bíi Igoni Barret, Alexis Okeowo, àti Connor Ryan (tí ìwé rẹ̀ tó ń bọ̀ lọ́nà lorí Nollywood bẹ̀rẹ̀ ní àkókò rẹ̀ ní CCA), ti ó sì ti wá rí ojú-ọjọ́ tí ó so èso ìrètí àti èròńgbà láti ìgbà náà.

The exhibition space at the CCA, Lagos. Image by author.
The exhibition space at the CCA, Lagos. Image by author.

CCA fẹ́ mú ìdàgbàsókè bá iṣẹ́-ọnà ní ìlú Lagos àti ilẹ̀ ibi tí ó wà lápapọ̀, bíi àjà kẹta tí a ti figi gún ní ibi tí yàrá-ìfàwòránhàn wà. Kì í kàn-án ṣe láti gbẹ́ ìran abẹ́lé àti ìsàtúngbédìde àkóónú iṣẹ́-ọnà ṣíṣẹ nìkan; ó tún fẹ́ di rírí fún gbogbo àgbáyé. Temitayo Ogunbiyi tí mo kọ́kọ́ ṣalábàápàdé àwòrán ìbánisọ̀rọ̀-lóríṣìíríṣìí rẹ̀ ní CCA, báyìí ti ń jókòó ìgbìmọ̀ oríṣiríṣi àwọn àjọ iṣẹ́-ọnà àgbááyé. Ó tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Adarí Iṣẹ́-Ọnà àti Adarí Aṣàfihàn-àwòrán ARTX Lagos láàrin ọdún 2018–2020. Ìpàtẹ iṣẹ́-ọnà àkọ́kọ́ jẹ́ fífilọ́lẹ̀ ní ọdún 2016. Gẹ́gẹ́ bí aṣàfihàn-àwòrán àkọ́kọ́, Bisi Silva ṣiṣẹ́ pẹ̀lú olùdásílẹ̀ Tokini Peterside láti ṣe ìṣẹ̀dá ìlànà àkóónú tí ó mú ìpàtẹ iṣẹ́-ọnà àtijọ́ mọ́ ètò-ẹ̀kọ́ àti ètò ìṣàfihàn àwòrán tí ó ní èròǹgbà láti ṣ̀agbédìde àti láti ṣe àtìlẹyìn ojú-ọjọ́ iṣẹ́-ọnà tuntun ní ìlú Lagos ní ọ̀nà tí kì í ṣe ti ìbilẹ̀.

CCA ti máa ń bu ọlá ó sì máa ń gbárùkù ti iṣẹ́ àti ètò-ṣíṣé tí ó yà kúrò lára àwòrán kúnkùn àti àwọn ọ̀nà ìbílẹ̀; iṣẹ́-ọnà tí ó fi ààyè gba ìwòdénú púpọ̀ síi tí ó sì ń mú àwọn òǹwòran rẹ̀ kópa tí ìdíwọ́ láti ráyè sí i sì kéré. Àkójọ àwọn oníṣẹ́-ọnà olóríṣiriṣi-ẹ̀ka tí a ṣàfihàn láti ọdún yìí wá tí wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ni àwọn bí i Jelili Atiku, Lemi Ghariokwu, Ndidi Dike, Olu Amoda, George Osodi, Taiye Idahor, Peter Okotor, àti Ngozi Omeje Jelili Atiku, Lemi Ghariokwu, Ndidi Dike, Olu Amoda, George Osodi, Taiye Idahor, Peter Okotor, àti Ngozi Omeje. Àtẹ̀jáde àwọn oníṣe-ọnà yìí àti iṣẹ́ wọn ti rìn kọjá yàrá-ìfàwòórànhàn ti àjà-kẹta CCA àti sí inú àwọn ìtàkurọ̀sọ, ipò ìtọ́kasí àwọn oníṣe-ọnà, àwọn ilé, ìfàwòórànhàn, àwọn ọlọ́dún méjì-méjì, àti àwọn ìpàtẹ káàkiri ìlú àti gbogbo àgbáyé. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ọdún 2007 ayàwòrán Jide Alakija ṣe ìdásílẹ ̀ àrà ìgbàlódé tuntun láti ṣe àfihàn bí a ṣe ń ya àwòrán ìgbéyàwó àti àwọn ayẹyẹ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ní gbígbé iṣẹ́ rẹ̀ wá sí sàkání àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní CCA nípasẹ̀ ìsàfihàn àwòrán tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ “Owambe, Aṣọ-Ebi, and the Politics Dress” (October 2011), ìjíròrọ̀yìí náà ti jẹ́ èyí tí wọ́n mọ̀ káàkiri àgbááyé..

Àjọ CCA tún tẹ̀síwaájú láti máa ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn ènìyàn tí wọ́n n gbìyànjú láti ní ilé iṣẹ́ tiwọn láti ṣe àfihàn àti láti bu olá fún eré-ṣíṣe olóríṣìí ọ̀nà, èyí tí Bísí mú ìdàgbàsókè bá, the Video Art Network Lagos (VAN) ní ọdún 2009 dìde láti ara àjọṣepọ̀ láàárín igbákejì afàwòránhàn Jide Anogwih àti Olùdarí isẹ́ ṣíṣe Oyinda Fakeye, pẹ̀lú àjọṣepọ̀ oníṣe-ọnà tó wà fún ìró Emeka Ogboh. Ní ọdún 2012 ní Freedom Park, “films4peace” VAN ṣe ìṣàfihàn fídíò àwọn oníṣe-ọnà tó lè ní mọ́kànlélógún káàkiri àgbáyé. Jù VAN lọ, Àjọ CCA ti pèsè ìpìlẹ̀ fún A
Whitespace/Untitled, The Revolving Art Incubator, hFactor, the Treehouse, àti No Parking; àwọn ètò bíi Invisible Borders, the Lagos Biennale, Tiwan Tiwa Street Art Festival, àti Dance Gathering láti ọwọ́ Qudus Onikeku; àwọn ayẹyẹ àti ìpàtẹ bíi ARTX Lagos, Lagos Theater Festival, àti Lagos Photo; ẹka ètò-ẹ̀kọ́ irúfẹ́ bíi the VAL Foundation3See also: A​igbokhaevbolo, O. (2023) Dreaming Art in an Unlikely Place, Interdependence, Yemisi Shyllon Museum, Rele Art Foundation, Yinka Shonibare’s GAS Foundation (Lagos), àti Victor Ekihamenor’s Angels & Muse.

Nígbà tí ìlú Lagos jẹ́ àkórí tó ń jẹyọ lemólemọ́ fún irú iṣẹ́ CCA tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, Pan-African model Àsìkò Art School jẹ́ èyí tó yàtọ̀ nínú pé ó ní òye ìdènà ìdàgbàsókè àyíká ààyè ilé-ẹ̀kọ́ tó dúró gbaari lórí ilẹ̀ náà. Nínú “All I have wanted” (2011), Iṣẹ́ àkànṣe Otobong Nkanga tí ó dá lórí eré-ṣíṣe sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìrántí wa àti ìtàn nípa àwòrán bí àlà-ilẹ ìlú Lagos ṣe rí. Àwòrán bí ìlú kan ṣe rí máa ń jẹ́ láti ara àwọn àmì àti kókó ohun tí a dánìkan rántí tàbí tí a pawọ́pọ̀ rántí, tí a fi pamọ́ sí orí ara, inú ìwé, inú omi, àti ara òkúta ilé. Fún ọdún márùndínlógún, àwọn ògiri CCA ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ilé ìdí nǹkan pamọ́ fún ìrọ̀rùn ìrántípadà àwọn àlá, àwọn ohùn, àwọn ìfihàn àti àwọn ìmọ̀lára ìbáṣepọ̀ tí a ṣẹ̀rị̀ ṣàwárí tàtí èyí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ túká. Àwọn igun àwọn ìwé yàrá- ìkàwé ń dúró pẹ̀lú àwọn íńkì sísán, àwọn epo, igi, irin, bébà, àti nǹkan yòókù tí oníṣe-ọnà, olùṣèwádìí, tàbí àwọn ọlọ́kàn ìtọpinpiǹ gbìyànjú láti dá ọwọ́ wọn lé láti wá ìtàn tàbí le sọ ìtàn kan.

Ní ìdà Kejì, bi Mo ṣe ń kọ èyí, àti lẹ́yìn ogún ọdún ní ìlú Lagos, Folarin ti wà nínú gbangba láti ṣe ìgbéyàwó tí yóò sìbẹ̀rẹ̀ ìgbé-ayé tuntun ẹlẹ́gbẹ̀lẹ́gbẹ máìlì jìnnà réré. Wọ́n rán mi létí ímeèlì kan tí Mo gba láti ọ̀dọ̀ Folarin ní oṣù kọkànlá ìparí ọdún 2009:

Gbèdéke ìforúkọsílẹ̀ fún èyí ní ọjọ́ Ẹtì 27. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yóò wáyé ní ààrin Ọjọ́ 8 oṣù Èrèlé sí ọjọ́ 6 oṣù Ẹrẹ́ná ọdún tó ń bọ̀, àti pé ìrírí náà yóò jẹrìí aláìlẹ́gbẹ́. Fi iṣẹ́ rẹ, ní bíbá onímọ̀ Fullbright Antawan sọ̀rọ̀ ní CCA ti tó fún ọ láti mú ọ bínú kọlu ìyàwòrán pẹ̀lú ọ̀nà tuntun! Mo gbọ́ pé àwọn ayàwòrán káàkiri Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà àti Gúúsù ilẹ̀ Áfríkà ti kàn sí Bisi Silver lórí èyí.

Tí ẹnikẹ́ni ò bá le wá sí CCA tó sì fẹ́ kí n bá òun gba fọ́ọ́mù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ṣíwájú ọjọ́ Ẹtì, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n mọ̀.

Folarin ò gbàgbé láti fi àlàkalẹ̀ ètò CCA tàbí lẹ́tà-aṣèròyìn ṣọwọ́ ránṣẹ́ sí mi rí.

Kò dámi lójú Iye ìgbà tí Mo ti wo ìran tó parí nínú eré Field of Dreams (1989), Ní ibi tí James Earl Jones ti kó ipa òǹkọ̀wé Terrance Mann. Eré náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ray (Kevin Costner), olú ẹ̀dá-ìtàn, tó ń gbọ́ ohùn ní àárín oko àgbàdo rẹ̀ (eléyìí tó ti tó àkókò láti kógbá wọlé), tó sọ pé: “Tí o bá kọ́ ọ, yóò wá.” Ó tẹ̀ síwájú láti kọ́ pápá ìṣeré-bọ́ọ́lù béèsì ní ààrin ibi tí a kò mọ̀, Iowa, USA. Ìgbéṣẹ̀ yìí mú àárín òun àti bàbá rẹ̀ gún padà, ṣùgbọ́n ohun tí ó ju èyí lọ máa ń so ọ̀pọ̀lọpọ̀ pọ̀ mọ́ àálá kan ṣoṣo. Eré náà parí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó gbajúgbajà láti ọwọ́ James Earl Jones àti àwòrán ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n dorí kọ ibùdó náà bí oòrùn ṣe ń wọ̀.

Mo gba oríṣiríṣi ímeèlì láti ọ̀dọ̀ Bisi Silva èyí tó buwọ́ lù pẹ̀lú: “WE BRING THE WORLD TO LAGOS AND WELCOME YOU TO OUR WORLD” ní kíkọtóbi, híhàn aláwọ̀ aró.

Nígbà kúgbà tí Folarin bá padà dé. Yóò mọ ọ̀nà àti rí the Center for Contemporary Art, Lagos (CCA). Ó wà níbi gbogbo.

Translated by Aremu Adeola

Interdependence (2022) is a collaboration between e-flux Architecture and OtherNetwork.

Papa Omotayo
Papa Omotayo is the CEO/Creative Director of MOE+ artARCHITECTURE and founder of A Whitespace Creative Agency (AWCA).