Gbígbèrò Í-̀na Níbi Táò Fkàn sí.

Oris Aigbokhaevbolo

April 18, 2023

Lagos, Interdependence

Surroundings of Vernacular Art-space Laboratory (VAL).
Surroundings of Vernacular Art-space Laboratory (VAL).

Igba ojúlé ló wọlé ikán ẹgbẹ̀rin ọ̀nà ló wọlé àwúrèbe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ rí tí èèyàn bá ń lọ sí ibùdó isẹ́-ọnà Vernacular Art-space Laboratory (VAL) nílùú tó wà ní òkè-odò ní Èkó. Akèrègbè ló ń júwe ibi tí wọ́n yóò ti okùn bọ̀ lára òun, apá ibi tí èèyàn bá ti ń bọ̀ ni yóò sọ bóyá èèyàn yóò fẹsẹ̀ rìn ni tàbí yóò gbé mọ́tò gba òpópónà kan tí àwọn orúkọ rẹ̀ rú ni lójú. Ọ̀tọ̀ ni orúkọ tí a mọ̀ òpópónà náà sí tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n orúkọ mìíràn tí fẹ́rẹ̀ẹ́ bò orúkọ yẹn mọ́lẹ̀ nísìnyí.

Bí a ṣe ń rìn lọ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ lọ sí VAL bẹ́ẹ̀ náà ni èmi àti, Aderemi Adegbite tí ó jẹ́ olùdásílẹ̀ ibùdó náà ń tàkurọ̀sọ. Adégbìtẹ́ sọ díẹ̀ fún mi nípa ìtàn àdúgbò náà. Ó ṣàlàyé pé ṣọ́ọ̀ṣí kan tí òun nàka sí nígbà tí à ń bọ̀ ló sọ òpópónà náà lórúkọ tuntun èyí tí í ṣe Ìyàọmọ́lérè. Mo wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí ni yóò ṣe tí òun fúnra rẹ̀ bá jẹ́ mọ̀lẹ́bí ìdílé tí wọ́n ń fi orúkọ wọn pé òpópónà náà tẹ́lẹ̀ ńkọ́. Adégbìtẹ́ fèsì pé gbogbo irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò jẹ òun lógún rárá. Ó wá ṣàlàyé pé tí ọkàn òun kò bá balẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà òun yóò yà lo àwọn oníròyìn láti tako àyípadà orúkọ náà ni.

Wàyí o, èrò tuntun jẹyọ. Bí a kò bá rí àdán ṣe ni à ń fi òòbẹ̀ ṣẹbọ, bí kò bá sí ilé tí wọn yóò lò Adégbìtẹ́ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ oníṣẹ́ ọnà yóò yà kúkú ṣe àmúlò gbogbo ibi tí wọ́n bá rí ni. Ọ̀rọ̀ Adégbìtẹ́ wá di ìrèké kò ní ibùdó, ibi gbogbo ló gba alágbára. Adégbìtẹ́ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yóò lo ibi tí kì í ṣe ilé pẹ̀lú àwọn ibi tí a lè lò dípò ilé. Ó ṣàpèjúwe ìsọ̀rí àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ibi tí wọ́n kò tíì lò rí rárá, ìsọ̀rí kejì sì ni àwọn ibi tí ó bójúmu tí ó sì wuyì tí àwọn ará ìlú ti ń lò tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé èrò tuntun yì í dára ó sì mú ìwúrí wá, síbẹ̀síbẹ̀ kò dàbí èròǹgbà àtilẹ̀wá tí Adégbìtẹ́ ní lọ́kàn pé kí ó ní ibùdó kan pàtó tí wọ́n yóò ti fi iṣẹ́ ọnà dárà tí ó wù wọ́n. Níní ibùdó kan pàtó fún iṣẹ́ ọnà kò kúrò lọ́kàn Adégbìtẹ́ ó sì ṣeé ṣe kí ọsàn èròǹgbà náà ó so dídùn lọ́jọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n lásìkò yì í omí pọ̀ lámù, àwọn nǹkan pàtàkì tí ó yẹ kí wọ́n ó tètè ṣe pọ̀ nílẹ̀ ó pọn dandan kí wọ́n ó jára mọ́ṣẹ́.

1. Approach to Vernacular Art-space Laboratory (VAL). Photo by author<br />
2. Approach to Vernacular Art-space Laboratory (VAL). Photo by author<br />
3. Adegbite in front of Vernacular Art-space Laboratory (VAL). Photo by author
1. Approach to Vernacular Art-space Laboratory (VAL). Photo by author<br />
2. Approach to Vernacular Art-space Laboratory (VAL). Photo by author<br />
3. Adegbite in front of Vernacular Art-space Laboratory (VAL). Photo by author
1. Approach to Vernacular Art-space Laboratory (VAL). Photo by author<br />
2. Approach to Vernacular Art-space Laboratory (VAL). Photo by author<br />
3. Adegbite in front of Vernacular Art-space Laboratory (VAL). Photo by author
1. Approach to Vernacular Art-space Laboratory (VAL). Photo by author
2. Approach to Vernacular Art-space Laboratory (VAL). Photo by author
3. Adegbite in front of Vernacular Art-space Laboratory (VAL). Photo by author

Ọdún 2016 ni wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ Ọdún Iṣẹ́-Ọnà Ìlú Ìwàyà èyí tí wọ́n pè ní The Ìwàyà Community Arts Festival (ICAF). Adégbìtẹ́ sọ pé òun fúnra òun lòun ṣe agbátẹrù ìnáwó àjọ̀dún náà bẹ́ẹ̀ lòun sì gbìyànjú pé àwọn akẹgbẹ́ òun káàkiri àgbáyé láti pé kí wọ́n dá iṣẹ́ wọn jọ láti kópa nínú ètò náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní ibùdó kan pàtó tí ó jẹ́ tiwọn, Adégbìtẹ́ àti ikọ̀ rẹ̀ kó fọ́tò sí gbogbo ibi tí fọ́tò bá ti lè dúró sí. Ìgbésẹ̀ yì í mú kí ṣíṣe ẹ̀ẹ̀kẹ́ èébú àti ṣíṣúra-ẹni-lóhùn wáyé nígbà tí wọ́n bá ń gbé fọ́tò kọ́ sí àwọn ààyè kan. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀ òru ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n àwọn alátakò kan yóò ti ré àwọn fọ́tò tí wọ́n gbé kọ́ lulẹ́ kí ilẹ́ ó tó mọ̀. Láìfọ̀tápè, àjọ̀dún náà kẹ́sẹjárí. Ní ọdún tí ó tẹ̀lé tí àkọ́kọ́, ọpọ́n àjọ̀dún náà (ICAF) ti sún síwájú, àrà tí ó ga ju ti ọdún èṣín lọ ti wà nínú ètò. Àwọn oniṣẹ́ ọnà tí wọ́n kópa pọ̀ ju ti ọdún àkọ́kọ́ lọ ààtò rẹ̀ sì tún dára ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Àwọn oniṣẹ́ ọnà kan kọ̀ láti wá sí Èkó. Adégbìtẹ́ sọ pé kò sí ìdí pàtàkì kankan tí ó fi yẹ kí ẹ̀rù wíwá sí Èkó bà wọ́n nítorí pé ” Èkó ni ààbò tí ó dájú wà jù ní gbogbo ibi tí mo mọ̀ ní àgbáyé. Ó kàn jẹ́ pé tipẹ́tipẹ́ ni Èkó ti ní ẹ̀rù lára ni” Adégbìtẹ́ ló sọ bẹ́ẹ̀ tẹ̀ríntẹ̀rín. Àwọn oniṣẹ́ ọnà márùn-ún láti orílèèdè mìíràn ló kopa ninu àjọ̀dún náà. Ṣe ni wọ́n gba ilé fún wọn láàrin ìlú tí àwọn náà sì darapọ̀ mọ́ àwọn ará ìlú. Àwọn ará ìlú fún àwọn oniṣẹ́ ọnà kan tí wọ́n wá kópa ní yàrá kan kódà àwọn mìíràn nínú àwọn ará ìlú kò kúrò nílé fún àwọn akópa. Ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà díẹ̀ sí pápá ìṣeré tí wọ́n ti ń gbá bọ́ọ̀lù, tí a sọ pé ó wà lábẹ́ wáyà iná ńlá yẹn, ni a ti rí ilé kan. A lè sọ pé ọ̀tọ̀lórìn ni ilé náà torí pé kò rí bí àwọn ilé tí a ti ń rí bọ̀ látẹ̀yìnwá. Ilé náà dúró kangídì bí èṣù Àwẹ̀lé. Ó dúró gbọn-in-gbọn-in bí òkè Olúmọ kò dàbí pé ọ̀wàrà òjò lè wó o lulẹ̀ rárá. Ibi tí a wí ni a dé yì í, ẹyẹ méjì kì í jẹ́ adìẹ, ilé náà ni ibùdó iṣẹ́ ọ̀nà Abúlé. Àjà ilẹ̀ ni ilé náà, páànù ni wọn sì fi ṣe òrùlé rẹ̀. Wọ́n fi ọ̀dà dúdú ya àwòrán oríṣiríṣi orí sí ẹ̀gbẹ́ ilé náà. Orúkọ ayàwòrán tí ó ṣiṣẹ́ náà ni Nature. Iṣẹ́ náà jẹ́ ọ̀kan lára ‘Àfikún’ (Postscripts) àwọn àfihàn iṣẹ́ ọnà tí ibùdó iṣẹ́ ọnà ní Abúlé (VAL)ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 2021. Nọ́nba ‘20’ tó hànde níbẹ̀ wà fún bíbu-ọlá-fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wáyé ní ogúnjọ́ oṣù Ọ̀wàrà (oṣù kẹwàá) ọdún 2020. Òru ọjọ́ náà ni èsúkè padà wọ rárà ìfẹ̀hónú-hàn láti dẹ́kun ìwà ìfìyà-jẹ-aláìṣẹ̀ tí àwọn ọlọ́pàá ń hù sí àwọn ọ̀dọ́ (END SARS). Ìfẹ̀hónú-hàn náà padà yọrí sí làásìgbò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ṣì ń ṣẹ́ kanlẹ̀ dòní kódà lẹ́yìn tí àwọn olùfaragbàyà rògbòdìyàn náà fi àwọn ibi tí wọ́n fi ṣèṣe hàn fáráyé.

Ó yẹ kí á sọ àsọyé wí pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí làásìgbò ló ṣokùnfà kíkọ́ tí wọ́n kọ́ ilé náà àmọ́ ó fara pẹ́ ìfẹ̀hónú-hàn. Nǹkan tí ara Ọlọ́jọ́ gbà ara Edì kò gbà á: nítorí náà àwọn tí kò fẹ́ràn yíyafọ́tò ní òpópónà tako irúfẹ́ iṣẹ́ ọnà Adégbìtẹ́. Adégbìtẹ́ sọ pé ” Àwọn kàn wulẹ̀ tako kí wọ́n ó máa ya fọ́tò ni àmọ́ wọn kò lè sọ èrèdí àtakò náà ” Àwọn ọmọ ìta gan-an náà á fẹ́ kí o sanwó fún àwọn lórí fọ́tò tí o bá yà láì ṣe wí pé ó kàn wọ́n lọ́wọ́-lẹ́sẹ̀. Wọ́n á ṣáà fẹ́ gbowó lọ́wọ́ ẹni. Àwọn ni ajínasẹ̀ tí ó fẹ́ máa jẹun ajígbọ́n-ọnni”. Nítorí kí Adégbìtẹ́ lè ní ìsinmi ló ṣe kúkú padà sí àdúgbò rẹ̀ kí ó lè máa bá iṣẹ́ àwòrán yíyà rẹ̀ lọ ní pẹrẹu torí pé tẹni-ń-tẹni ti àkísà ni ti àkìtàn. Lásìkò yì í gan-an ló bẹ̀rẹ̀ sí ní gbèrò bí òun yóò ṣe dá ibùdó iṣẹ́ ọnà kan sílẹ̀. Adégbìtẹ́ sàlàyé pé ” Èrò náà wá sí mi lọ́kàn lásìkò tí mò ń gbìyànjú láti ṣípòpadà kúrò nípò ayàwòrán alákọsílẹ̀ lọ sí ipò ayàwòrán aláròjinlẹ̀” Adégbìtẹ́ túbọ̀ ṣàlàyé pé ” Gbogbo ohun tí mo nílò ni kulu. N kò nílò láti máa tọ títí kiri torí pé mo lè ṣe àpópọ̀ gbogbo èròǹgbà wọ̀nyí ní ojúkan ibi tí mo bá wà. Gẹ́gẹ́ bí Adégbìtẹ́ tí sọ, ohun tí ó lérò pé kí ó jẹ́ ààyè kékeré tí ayàwòrán yóò fi gbé èròǹgbà rẹ̀ kalẹ kí ó lè móríbọ́ kúrò nínú pákáleke àárín ìgboro ló ti wá gbèrú yì í. Akérémọdò ti paradà ó di òkun alagbalúgbú omi, ìrì wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ ti paradà ó di ọ̀wàrà òjò. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé ìbéèrè kan wà tí Adégbìtẹ́ kò wá ìdáhùn rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀: Akáse tí àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n jọ jẹ́ oníṣẹ́ ọnà bá wá kí i tí wọ́n sì fẹ́ ṣe àwọn iṣẹ́ kan báwo ni ààyè kékeré náà yóò ṣe gbà wọ́n. Báwo ni ìka méjì yóò ṣe wá wọ ìwo ẹtu báyìí ? Ó ṣe pàtàkì kí ó pawodà kí ó tún awo ṣe nípa sísọ èròǹgbà rẹ̀ di ńlá. Lédè kan, bí èrò ṣíṣe ìdásílẹ̀ Ibùdó Ìṣẹ́ ọnà Abúlé (Vernacular Art-space Laboratory) ṣe wáyé nìyẹn. Àwọn Yorùbá sọ pe ọwọ́ gẹ-n-gẹ ló ń ṣáájú ijó, ẹsẹ̀ ló ń ṣáájú ìrìn bẹ́ẹ̀ sì ni ilẹ̀ ni ó kọ́kọ́ ṣe pàtàkì tí a bá fẹ́ kọ́lé. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tí Adégbìtẹ́ gbé ni ilẹ̀ rírà. Adégbìtẹ́ sọ pé ẹ̀ẹ̀méjì lòun sanwó ilẹ̀ fún ìdílé kan tí ó ta ilẹ̀ fún òun. Lẹ́yìn-ọ̀rẹyin ló hàn sí pé ilẹ̀ ìjọba àpapọ̀ ni torí pé ara ilẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Èkó ni ilẹ̀ náà. Yunifásítì Èkó kò jìnnà sí agbègbè náà. Nígbà tí orí yóò ṣe Adégbìtẹ́ lóore àwọn aláṣẹ Yunifásítì náà kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí lílo ilẹ̀ náà. Èyí fún Adégbìtẹ́ ní àǹfààní láti dúró lórí ilẹ̀ náà.

Surroundings of Vernacular Art-space Laboratory (VAL).  Photo by author
Surroundings of Vernacular Art-space Laboratory (VAL). Photo by author

Ní ọjọ́ òní, Ibùdó Iṣẹ́ Ọnà Abúlé (VAL) wà ní ààyè kan ní etí omi tí koríko ibẹ̀ kàn fi díẹ̀ ga ju kókósẹ̀ lọ ni. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ ilé náà ṣe ni igbó kún bò ó mọ́lẹ̀ wọ́n sì nílò láti ṣán igbó náà. Owó ní tí òun kò bá sí nílé kí ẹnikẹ́ni má ṣe dábàá nǹkan kan, owó ni kẹ̀kẹ́ ìyìnrere, owó ṣe pàtàkì, ó ṣe kókó. Kí èròǹgbà rẹ̀ lè wá sí ìmúṣẹ, Adégbìtẹ́ ṣètò ẹ̀dáwó ọlọ́pọ̀ èrò ní ẹ̀ẹ̀méjì. Ìgbà àkọ́kọ́ ó rí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin owó dọ́là kò jọ, ó sì tún padà kó ẹgbẹ̀rin dọ́là jọ ní ìgbà kejì. Àpapọ̀ owó yì í kò lè ṣe é fi kọ́ nǹkan kan rárá. Gẹ́gẹ́ bí Adégbìtẹ́ ṣe wí, tipátipá ni owó náà fi tó ó ṣe ìpìlẹ̀ ilé náà.

Lédè kan àwọn mẹ̀kúnnù ti gbà pé ó ti di dandan kí àwọn gba owó gbà-má- bìínú lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n bá ń jẹ àǹfààní lára ìlú àwọn. Adégbìtẹ́ kò fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ nípa ìbínú àti àìdunnú rẹ̀ nípa ìwà ìlọ́nilọ́wọ́gbà tí wọ́n ń hù náà. Àmọ́ èmi rò pé Adégbìtẹ́ lè bá wọn ṣe ìdúnàádúrà ju bí àwọn ẹlòmíràn ṣe lè bá wọn ṣe é lọ. Nígbà tí ó jẹ́ pé àdúgbò náà ni wọ́n ti bí i tí wọ́n sì ti wò ó dàgbà. Síbẹ̀ náà inú rẹ̀ kò dùn sí nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀.

Ní ìparí ọdún 2017 ni Adégbìtẹ́ ti fi Ibùdó Iṣẹ́ Ọnà Abúlé (VAL) sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba bẹ́ẹ̀ náà ló sì ti gba gbogbo ìwé ìforúkọsílẹ̀ sọ́wọ́ èyí ló sì fún wọn ní àǹfààní láti lè dáwọ́lé ṣíṣe àwọn iṣẹ́ àkànṣe.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2018 ni Adégbìtẹ́ ṣe alábàápàdé ìpè fún àbá láti jẹ àǹfààní ètò ìrànlọ́wọ́ owó tí àjọ Prince Claus Fund gbé kalẹ̀ tí wọ́n forí rẹ̀ sọ ṣíṣàtìlẹ́yìn ” Sísọ̀rọ̀ Àṣà Fún Àwọn Ọ̀dọ́ àti Pẹ̀lú Àwọn Ọ̀dọ́” (Cultural expression for and with young people) Adégbìtẹ́ dábàá iṣẹ́ àkànṣe kan tí ó pè ní Àtúnwòye Àwùjọ (Communal Re-Imagination) Iṣẹ́ àkànṣe yì í yóò mú kí ilé-iṣẹ́ ọnà rẹ̀ àti àwọn ọ̀dọ́ ìlú yóò jọ bá ara wọn ṣiṣẹ́ fún odidi ọdún kan gbáko. Àjọ Prince Claus Fund gba àbá náà wọlé ilé-iṣẹ́ ọnà sì gba owó tí ó lé díẹ̀ ní ọ̀kẹ́ kan (ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún) owó yúrò.

Lédè kan àwọn mẹ̀kúnnù ti gbà pé ó ti di dandan kí àwọn gba owó gbà-má- bìínú lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n bá ń jẹ àǹfààní lára ìlú àwọn. Adégbìtẹ́ kò fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ nípa ìbínú àti àìdunnú rẹ̀ nípa ìwà ìlọ́nilọ́wọ́gbà tí wọ́n ń hù náà. Àmọ́ èmi rò pé Adégbìtẹ́ lè bá wọn ṣe ìdúnàádúrà ju bí àwọn ẹlòmíràn ṣe lè bá wọn ṣe é lọ. Nígbà tí ó jẹ́ pé àdúgbò náà ni wọ́n ti bí i tí wọ́n sì ti wò ó dàgbà. Síbẹ̀ náà inú rẹ̀ kò dùn sí nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀.

Akudaaya a performance by Yusuf Durodola. Photo by VAL Workstation
Akudaaya a performance by Yusuf Durodola. Photo by VAL Workstation
Akudaaya a performance by Yusuf Durodola. Photo by VAL Workstation

Ní ìparí ọdún 2017 ni Adégbìtẹ́ ti fi Ibùdó Iṣẹ́ Ọnà Abúlé (VAL) sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba bẹ́ẹ̀ náà ló sì ti gba gbogbo ìwé ìforúkọsílẹ̀ sọ́wọ́ èyí ló sì fún wọn ní àǹfààní láti lè dáwọ́lé ṣíṣe àwọn iṣẹ́ àkànṣe.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2018 ni Adégbìtẹ́ ṣe alábàápàdé ìpè fún àbá láti jẹ àǹfààní ètò ìrànlọ́wọ́ owó tí àjọ Prince Claus Fund gbé kalẹ̀ tí wọ́n forí rẹ̀ sọ ṣíṣàtìlẹ́yìn ” Sísọ̀rọ̀ Àṣà Fún Àwọn Ọ̀dọ́ àti Pẹ̀lú Àwọn Ọ̀dọ́” (Cultural expression for and with young people) Adégbìtẹ́ dábàá iṣẹ́ àkànṣe kan tí ó pè ní Àtúnwòye Àwùjọ (Communal Re-Imagination) Iṣẹ́ àkànṣe yì í yóò mú kí ilé-iṣẹ́ ọnà rẹ̀ àti àwọn ọ̀dọ́ ìlú yóò jọ bá ara wọn ṣiṣẹ́ fún odidi ọdún kan gbáko. Àjọ Prince Claus Fund gba àbá náà wọlé ilé-iṣẹ́ ọnà sì gba owó tí ó lé díẹ̀ ní ọ̀kẹ́ kan (ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún) owó yúrò.

Yorùbá bọ̀ wọ́n sọ pé ohun tí ó ń dun ni ló ń pọ̀ nínú ọrọ̀ ẹni, ológún ẹrú kú, aṣọ rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan. Adégbìtẹ́ mú ọ̀rọ̀ ilé tí wọn yóò ti máa ṣe iṣẹ́ ọnà ní ọ̀kúnkúndùn torí náà ni ó ṣe mẹ́nu bà á nínú àkóónú àgbékalẹ̀ àbá rẹ̀ pé Ilé-iṣẹ́ ọnà Abúlé (VAL) yóò kọ́ ilé kan tí àwọn oniṣẹ́ ọnà yóò ti máa ṣe àfihàn iṣẹ́ ọnà wọ́n. Nítorí náà ṣe ni Adégbìtẹ́ padà sí orí ilé kíkọ tí ó ti patì nígbà kan tí ó sì tún ń kọ́ ilé náà lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún kan péré ni yóò fi jẹ àǹfààní owó ìrànwọ́ náà, ó ronú jinlẹ̀ pé ” Èé ṣe tí òun kò ṣe kúkú kọ́ ilé tí àwọn ọ̀dọ́ oniṣẹ́ ọnà wọ̀nyí a máa lò ní àlòtúnlò kódà lẹ́yìn tí ọdún kan bá ti parí?”

Yorùbá sọ pé ẹlẹ́rù ló ń gbé ẹrù kí a tó ba ké ọfẹ, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ ìnáwó lórí ìgbélárugẹ iṣẹ́ ọnà ṣe rí lọ́dọ̀ Adégbìtẹ́, òun ló ná owó tí ó pọ̀ jù lórí àkànṣe iṣẹ́ náà. Èròǹgbà Adégbìtẹ́ ni láti gbé iṣẹ́ ọnà kalẹ̀ fún àwọn ará ìlú. Ṣùgbọ́n báwo ni àwọn ará ìlú ṣe tẹ́wọ́gba akitiyan rẹ̀? Irú ìhà wo ni wọ́n kọ si? Adégbìtẹ́ sọ pé “Nígbà mìíràn wọn a ṣe àtakò rẹ̀” Ó ṣàkíyèsí pé àwọn olùgbé agbègbè náà kò pilẹ̀ kàwé dàbí alárà. Ó wòye pé kì í ṣe pé wọ́n ń tako òun torí pé wọn kò fẹ́ràn nǹkan tí òun ń ṣe ṣùgbọ́n wọ́n ń takò ó torí pé wọ́n gbàgbọ́ pé ó yẹ kí àwọn náà ó máa rí nǹkan gbà níbẹ̀, wọ́n fẹ́ gbẹ́nu si, àwọn náà fẹ́ máa rí nǹkan pọ́nlá. Àṣà jẹ-ń-bẹ̀ tí Adégbìtẹ́ ń tọ́ka sí yì í wọ́pọ̀ ní àwọn àdúgbò tí mẹ̀kúnnù bá ti pọ̀ ní ìlú Èkó. Ìṣọ̀wọ́ àwọn mẹ̀kúnnù bẹ́ẹ̀ gbàgbọ́ pé ṣe ni àwọn kan ń fi àwọn pawó torí náà ó pọn dandan kí kí àwọn ó fi ipá gba ẹ̀tọ́ àwọn ní ọwọ́ kí àwọn onítọ̀hún tó yọrí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Wọ́n ti sọ àpọ́nlé di ibà. Ìwà aṣa àti àìnítìjú ni èyí àmọ́ ó ti di bárakú wọ́n sì ti sọ di òfin àtọwọ́dá ní ìlú Èkó. Tí a bá fi abala ojú àánú wo àṣà yì í a lè sọ pé àbájáde ìwà kí ìjọba máa fi nǹkan falẹ̀ ni. Nígbà tí àwọn olùgbé agbègbè olówó bá ń fúnra wọn ṣe àwọn nǹkan amáyédẹrùn tí ìjọba kọ̀ tí kò ṣe fún wọn, àwọn olùgbé agbègbè àwọn mẹ̀kúnnù kò ní agbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwà ẹni - a - lè-mú-là-ń-lẹ̀dí-mọ́ ni wọ́n máa ń gùnlé. Wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn gbọ́dọ̀ fi ipá àti agídí gba nǹkan lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n bá ń ṣe nǹkan abiyì láti ara ìlú àwọn. Oṣù mẹ́ta ni wọ́n fi kọ́ ilé náà, lóòótọ́ ni ilé náà yàtọ̀ gédéńgbé sí àgbékalẹ̀ àwòrán ilé tí wọ́n kọ́kọ́ yà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ọ̀dá owó ló sì fà á tí ó fi rí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó di ìparí ọdún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn oniṣẹ́ ọnà bí - oníjó, ayàwòrán àti àwọn òṣèré orí ìtàgé ni wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ jáde níbi ètò Àtúnwòye Àwùjọ tí Ibùdó Iṣẹ́ Ọnà Abúlé gbé kalẹ (VAL’s Communal Reimagination. Ọ̀kan nínú àwọn olóríire náà ni Olúfẹlá Ọmọkẹ́kọ̀ bẹ́ẹ̀ ni òun àti ibùdó ṣì jọ ń ṣe àṣepọ̀ títí di àkókò yì í.

Àjọ̀dún Iṣẹ́-Ọ̀na ìlú Ìwàyà kò wáyé ní ọdún 2019. Ìwà ìdìtẹ̀-mọ́-ara-ẹni tí Adégbìtẹ́ hù ni kò jẹ́ kí wọ́n ó ṣe àjọ̀dún náà. Nítorí pé àwọn ará ìlú ń fi ẹ̀sùn kàn án pé bí ó ṣe ń rí owó tó níbi àjọ̀dún náà kò fún àwọn ní ẹ̀tọ́ àwọn bẹ́ẹ̀ sì ni ẹnìkan kì í jẹ kílẹ̀ ó fẹ̀. Adégbìtẹ́ wá fẹ́ kí wọ́n ó mọ̀ pé ewúro tòun kò fi ti òjò korò bẹ́ẹ̀ sì ni àfikún ni ẹbọ oríta jẹ́ fún ajá, ọ̀kọ́ ń jẹ́un nílé olówó rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Adégbìtẹ́ fẹ́ kí ó yé àwọn ará ìlú pé ó ṣeé ṣe fún òun láti gbé ìgbésí ayé ìdẹ̀rùn láì ṣe àjọ̀dún náà. Adégbìtẹ́ pinnu láti bẹ̀rẹ̀ àjọ̀dún náà padà ní ọdún 2020 ṣùgbọ́n bí àlejò ọ̀ràn ṣe wọlé dé wẹ́rẹ́ nìyẹn, àlejò náà ni àjàkálẹ́ àrùn kòrònà tí wọ́n pè ní Covid-19. Bàtá jákùn ó di ìkàlẹ̀, àjọ̀dún Iṣẹ́ Ọnà kò ṣe é ṣe mọ́. Ṣísé tí ìjọba sé àwọn ará ìlú mọ́lé túbọ̀ mú ìnira bá ọrọ̀-ajé àwọn ará ìlú pàápàá julọ láàrin àwọn mẹ̀kúnnù. Adégbìtẹ́ sọ pé òun nawọ́ ìrànwọ́ sí àwọn ará ìlú láti lè dẹ́rọ̀ ìnira tí òfin ìsémọ́ mú bá wọn. Orí Adégbìtẹ́ sọọre, àtìlẹ́yìn ìránwọ́ owó tí kò nírètí wọlé wẹ́rẹ́ láti ọ̀dọ̀ Àjọ Prince Claus Fund. Àjọ náà ránṣẹ́ sí VAL pé òun yóò fún ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún owó yúrò gẹ́gẹ́ bí ‘owó ìdẹ̀rùn’. Ìròyìn ayọ̀ yì í ló gún ikọ̀ Adégbìtẹ́ ní kẹ́ṣẹ́ láti tún ní èròǹgbà lórí iṣẹ́ ọnà lẹ́ẹ̀kan si.

Adégbìtẹ́ sọ pé ọ̀nà àbáyọ àti ọ̀nà ìgbàlà ni ó jẹ́ fún Kẹ́kọ̀ láti darapọ̀ mọ́ ètò náà pàtàkì jù lọ tí òun fúnra rẹ̀ tún padà di oniṣẹ́ ọnà. Kí Kẹ́kọ̀ ó tó darapọ̀ mọ́ ètò tí VAL gbé kalẹ̀ iṣẹ́ akọ̀wé ló ń ṣe bẹ́ẹ̀ náà ló sì tún ń kàwé lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan láti di akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ olùṣírò - owó. Kẹ́kọ̀ ti lulẹ́ ní àìmọye ìgbà nínú ìdánwò àjọ olùṣírò owó tí wọ́n ń pè ní ICAN, àjọ náà gbajúmọ̀ fún líle tí ìdánwò wọn máa ń le koko bí ojú ẹja. Kẹ́kọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí ní páyà ominú ń kọ ọ́ ẹ̀rù sì ń bá a torí kò mọ bí yóò ṣe lu àlùyọ ní ìgbésí ayé rẹ̀. ” Mò ń ronú pé ” Báwo ni máa ṣe ráyé gbé? Báwo ni máa ṣe rí bátiṣé? Báwo ni máa ṣe rọ́nà gbé e gbà? Ọ̀nà tí mo mọ̀ náà ni mò ń tọ̀ yì í. Ta ni máa ro tèmi fún báyìí? Tèmí mà bá mi láyé mi o! Kí ni mo tún fẹ́ ṣe báyìí?!” Orí ìkànnì ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ lórí ayélujára ‘Facebook’ ni Kẹ́kọ̀ ti rí ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè pèsìjẹ àti ìdùnràn rẹ̀: Kẹ́kọ̀ rí ìpè pé kí wọ́n wá darapọ̀ mọ́ ètò Àtúnwòye Àwùjọ (Communal Reimagination) Ohun tí ó bá ti yá kì í pẹ́ mọ́ a dífá fún àwòdì tí ó ń re Ìbarà tí afẹ́fẹ́ ta á ní ìdí pẹ́ẹ́: bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ Kẹ́kọ̀ ṣe ni ó bẹ́ mọ́ àǹfààní yì í. Kẹ́kọ̀ sọ pé ṣe ni òun kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀ pé kí òun lọ ṣe eléyìí fún ọdún kan kí òun fi ìdánwò olùṣírò owó ṣe àbọ̀wábá bí ti pèrègún igbódù.

Nípasẹ̀ ìrànwọ́ owó iṣẹ́ àkànṣe, Adégbìtẹ́ pèsè oúnjẹ àti ilégbèé fún Kẹ́kọ̀ àti àwọn yòókù rẹ̀ fún odidi ọdún kan tí wọ́n fi ṣe ètò náà. Ọdún kan yẹn ló Kẹ́kọ̀ padà sí rere. Kẹ́kọ̀ sọ àsọyé pé òun yọrí ètò náà pẹ̀lú àmọ̀dájú. Ó tún ìdánwò àjọ olùṣírò owó (ICAN) ṣe ó sì ṣe àṣeyege. Ṣùgbọ́n kò padà sí ẹnu iṣẹ́ tí ó ti kúrò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó tẹ̀síwájú pẹ̀lú iṣẹ́ ọnà. Àwọn ààrò mẹ́ta tí kì í da ọbẹ̀ nù tí wọ́n jẹ́ orísun ìṣípayá rẹ̀ tí ó sọ ọ́ di òṣèré oniṣẹ́ ọnà ni ìrírí rẹ̀, ìyá rẹ̀ tí ó ti di olóògbé pẹ̀lú àyíká tí ó wà. Kẹ́kọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ ọnà alátinúdá-ìtàgé.

Ìṣòro ilégbèé bá Kẹ́kọ̀ fínra fún ìgbà díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò níbi tí VAL pèsè fún un. Ibòmíràn lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ni Kẹ́kọ̀ ń gbé lásìkò tí a jọ sọ̀rọ̀, àmọ́ ó ń dà á rò pé kí òun padà sí Ìwàyà. Ó sọ pé Ìwàyà ni wọ́n ti bí òun ti wọ́n sì ti wo òun dàgbà. Kẹ́kọ̀ sọ pé ọ̀pọ̀ nǹkan lòun lè ṣe àfihàn fún àgbáyé láti ìlú Ìwàyà. Ó sọ pé tí òun kò bá ní parọ́ tí òun kò sì ní sèké pẹ̀lú ìrírí tí òun ní òun kò gbọdọ̀ jìnnà sí orísun ìṣípayá òun kí òun tó lè ṣe irú iṣẹ́ tí òun ń ṣe torí pé bí odò bá ti gbàgbé orísun rẹ̀ gbígbẹ ni yóò gbẹ.

Kẹ́kọ̀ ni Alábòójútó Àjọ Ibùdó Ilé-Iṣẹ́ Ọnà Abúlé (VAL) nísìnyí. Ọdún 2019 ni wọ́n kọ́ ilé náà parí. Ibùdó náà ti ṣètò àpérò àti àfihàn iṣẹ́ ọnà láti ìgbà tí wọ́n ti yọrí ilé náà àmọ́ wọ́n ní àwọn ìpèníjà. Ìpèníjà ńlá kan wáyé ní ọdún 2019 tí wọ́n kọ́ ibùdó náà parí. Àwọn jàǹdùkú lọ tú gbogbo ilé náà yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ wọ́n sì ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tí a fi so ẹ̀mí yàrá ìkàwé-yáwèé ró jẹ́. Adégbìtẹ́ sọ fún oníròyìn kan nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí ó bá ṣe nígbà tí ó ṣe àpèjúwe nǹkan tí ó rí pé ” Ìdààmú ọkàn bá wá pẹ̀lú iye àwọn ìwé tí a kò rí nínú àwọn pẹpẹ ìkówèésí. A wà gbogbo kọ̀rọ̀ ibùdó ṣùgbọ́n àwọn páálí tí wọ́n fi bo ìwé níwájú àti ẹ̀yìn nìkan ni a rí nínú àpò ìdalẹ̀nù… Wọn ti kó àwọn àkóónú ìwé gangan lọ. Wọ́n kàn da páálí ẹ̀yìn wọn sínú ìdalẹ̀nù ni, ẹyẹ́ ti lọ ìtẹ́ ti dòfo ” Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 2021 ni wọ́n ṣe àfihàn “Àwọn Àfikún” (Postscripts) ní ibùdó náà (VAL). Ní ọ̀tẹ̀ yì í, àwọn ará ìlú kò ipa púpọ̀ lórí àbájáde ètò náà. Ṣe ni àwọn èrò rọ́ wá síbẹ̀ láti wòran. Adégbìtẹ́ wòye pé tìtorí pé àjàkálẹ́ àrùn Covid-19 tí ká àwọn èèyàn lọ́wọ́ kò púpọ̀ láti kópa níbi eré ìdárayá ìta gbangba” ṣe ni ibẹ̀ kùn fọ́fọ́ ” Ó tún wòye pé ilé jíjókòó sí ti ṣú àwọn èèyàn”.

Àrà ọ̀tọ̀ ni Adégbìtẹ́ fi ètò náà ṣe torí pé àwọn òṣèré oniṣẹ́ ọnà tí wọ́n wà ní àwọn ìlú tí wọ́n wá ní agbègbè ni wọ́n kópa nínú ètò náà. Kàkà kí Adégbìtẹ́ ó kó àwọn akópa wá sí Ìwàyà ní ibùdó rẹ̀ ní ṣe ló kúkú lọ gbé ètò náà ká wọ́n mọ́lé ní àwọn ìlú bí Bàrígà tí òun náà jẹ́ ọ̀kan nínú ìlú àwọn mẹ̀kúnnù tí ó wà ní Òkè-Odò Èkó. Oniṣẹ́ ọnà tí ó fakọyọ gẹ́gẹ́ bí ìràwọ̀ òṣèré, bí Adégbìtẹ́ ṣe sọ, ni Kẹ́kọ̀. Iṣẹ́ ọnà tí ó fi dárà ni pádi ata tí ó dì sínú àwọ̀n tí ó tẹ̀ mọ́ ara páálí kí ó tó wá so wọ́n rọ̀ sí ara ògiri àti àjà VAL. Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀ ìṣòro àìrówóná tó bí ó ṣe yẹ ṣì ń bá wọn fínra ní VAL. Kí ó tó di ìgbà tí Adégbìtẹ́ sọ fún mi nípa òkìkí tí Kẹ́kọ̀ ní lẹ́yìn ètò ìṣàfihàn náà ni Kẹ́kọ̀ ti ń ráhùn pé òun kò ní owó tí ó lè tó òun láti ná lórí àkànṣe iṣẹ́ ọnà kan tí òun ń pòpọ̀ fún ṣíṣe ní ibùdó náà. Mo sọ nǹkan tí Kẹ́kọ̀ sọ fún mi létí Adégbìtẹ́, ó sì fèsì ní gbólóhùn kan pé ” Kí ó lò ó bẹ́ẹ̀”. Ó ṣàlàyé pé olójú kan tí kò mọyì ni Kẹ́kọ̀, ó di ìgbà tí ó bá rí afọ́jú, ó ní tí kì í bá ṣe tí ètò ìṣàfihàn tí àwọn n ṣe láti ọdún 2021 ni, Kẹ́kọ̀ ibà má ní nǹkan kan lọ́wọ́ rárá, ṣe ni awo rẹ̀ ìbá sùn lébi.

Níbi ètò ìṣàfihàn yì í kan náà ní ọdún méjì sẹ́yìn, Adégbìtẹ́ fúnra rẹ̀ ṣe àgbékalẹ̀ àkànṣe iṣẹ́ fọ́tò kan, níbẹ̀ ló ti ṣe àfihàn àwọn fọ́tò pélébé ti ara rẹ̀ láti fi bí àwọn ayàwòrán ti ṣe ya òun lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà látẹ̀yìnwá. Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, ó dàbí pé ètò náà tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ó wí pé ” Ìyẹn ni ìṣàfihàn tí ó lààmìlaaka jù lọ tí a ti ṣe níbí. Àwọn èèyàn tú jáde síta! Wọ́n wà káàkiri níbi gbogbo”.

Ní ọdún 2021, Ibùdó Iṣẹ́ Ọnà Abúlé (VAL) tún gba ìrànwọ́ owó láti ọ̀dọ̀ Àjọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì (British Council) fun apá kejì ètò Àtúnwòye Àwùjọ. Ikọ̀ VAL wá ṣe àkíyèsí ohun ìyanu kan lọ́tẹ̀ yí : ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n kọ lẹ́tà fún kíkópa wá láti agbègbè tí àwọn olówó wà nítòsí Ìwàyà. Eléyìí ya ni lẹ́nu torí kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ní Èkó kí àwọn olówó àti mẹ̀kúnnù ó máa farakínra lóde àríyá tí àwọn mẹ̀kúnnù. Ṣùgbọ́n tìmùtìmù Adégbìtẹ́ kò kọ́minú alábàrá, ó lòun kò ní jẹ́ kí wọ́n fa òun sí ìrìn irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé ” Nǹkan tí ó ṣe pàtàkì jù lọ fún òun ni bí iṣẹ́ tí òun gbé kalẹ̀ yóò ṣe di igi àlọ́yè” Bí Adégbìtẹ́ se wí nìyẹn bí a ṣe ń rìn padà lọ sí ibi tí ọkọ ọlọ́pọ́n tí ó gbé wa wá sí ìlú náà wà.

Inú ẹni kì í dùn kí á pa á mọ́ra. Àṣeyọrí ńlá ni a ṣe torí pé Kẹ́kọ̀ ṣe àmúlò ibùdó wa yì í. Àwọn ẹlòmíràn náà sì tún ṣe àmúlò rẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n yóò sì tún padà máa ṣe àmúlò rẹ̀ fún iṣẹ́ wọn. Ọ̀rọ̀ mi kò gba ẹjọ́ wẹ́wẹ́ àfi kí n máa dúpẹ́ ló tọ́. Nítorí náà mo dúpẹ́ mo dú pẹ̀pẹ́ òkun lọ́wọ́ Àjọ Prince Claus Fund tí wọ́n fún wa ní àǹfààní owó ìrànwọ́. Ọpẹ́ olóore àdáàdátán! Àjọ náà ló sọ àbá wa lórí ibùdó isẹ́ ọnà di àmúṣẹ tí wọ́n kò jẹ́ kí àrà náà ó rá mọ́ wá nínú. Ibùdó tí a kọ́ sí ọ̀kan tẹ́lẹ̀ wọ́n ti jẹ́ kí a sọ ọ́ dilé aláruru.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀ tí a ti rìn sókè-sódò ní òpópónà olórúkọ méjì ní Ìwàyà ni mo gba àtẹ̀jíṣẹ́ lẹ́tà ayọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Adégbìtẹ́. Kókó inú àtẹ̀jíṣẹ́ náà ni pé Ibùdó Ilé-Iṣẹ́ Ọnà Abúlé (VAL) ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe tuntun kan tí ó pè ní Alátagbà Ibùdó Ilé-Iṣẹ́ Ọnà Abúlé (VAL Satellite Lab) Èròǹgbà iṣẹ́ àkànṣe náà ni láti ṣe àgbékalẹ̀ ibùdó ilé - iṣẹ́ ọnà ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdírì mẹ́rin ní ìlú rẹ̀. Ìgbésẹ̀ náà sì ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìkan nínú àwọn ilé-ẹ̀kọ́ náà. Adégbìtẹ́ sọ àsọyé nínú àtẹ̀jíṣẹ́ náà wí pé ìrètí àwọn ni pé àwọn ilé-ẹ̀kọ́ mẹ́ta yòókù náà yóò yọ̀nda ààyè tí àwọn yóò lò fún iṣẹ́ àkànṣe náà.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ṣe àbẹ̀wò lọ sí ìlú náà yóò máa retí àbájáde kan náà.

Translated by Álímì-Adéníran Ọmọ́ṣaléwá

Interdependence (2022) is a collaboration between e-flux Architecture and OtherNetwork.

Notes:
1. “Demolition starts at Makoko slum,” Vanguard, 16 July, 2023. See vanguardngr.com/2012/07/demolition-starts-at-makoko-slum

2. Fisayo Soyombo, “PORTRAITS OF BLOOD (II): Names, Photos, Videos… How Lekki #EndSARS Protesters Were Massacred,” Foundation of Investigative Journalism, October 20, 2021. See fij.ng/article/portraits-of-blood-ii-names-photos-videos-how-lekki-endsars-protesters-were-massacred

3. VAL had previously received a grant for €2,000 from the Dutch embassy in 2017, to support the visit and participation of a Dutch artist in an ICAF artist-in-residence program.

4. Gregory Austin Nwakunor, “The agony of culture activist, Aderemi,” The Guardian, March 3, 2019. See guardian.ng/art/the-agony-of-culture-activist-aderemi

5. Reuters reported on his work and it was picked up by the New York Post. See reuters.com/world/africa/nigerian-artists-exhibition-showcases-food-preservation-methods-2023-01-27, and nypost.com/2021/02/05/nigerian-artist-creates-rotting-exhibit-as-coronavirus-warning

6. As part of the grant requirements, VAL collaborated with Site Gallery in Sheffield, UK.

Oris Aigbokhaevbolo
Oris Aigbokhaevbolo is a writer and critic based in Lagos; he's a cofounder of the Africa-focused Efiko Magazine.